بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَـٰنِ ٱلرَّحِيمِ
ٱقْرَأْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلَّذِى خَلَقَ ﴿١﴾
96:1 Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.
خَلَقَ ٱلْإِنسَـٰنَ مِنْ عَلَقٍ ﴿٢﴾
96:2 Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.
ٱقْرَأْ وَرَبُّكَ ٱلْأَكْرَمُ ﴿٣﴾
96:3 Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.
ٱلَّذِى عَلَّمَ بِٱلْقَلَمِ ﴿٤﴾
96:4 Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.
عَلَّمَ ٱلْإِنسَـٰنَ مَا لَمْ يَعْلَمْ ﴿٥﴾
96:5 Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.
كَلَّآ إِنَّ ٱلْإِنسَـٰنَ لَيَطْغَىٰٓ ﴿٦﴾
96:6 Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà
أَن رَّءَاهُ ٱسْتَغْنَىٰٓ ﴿٧﴾
96:7 nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.
إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجْعَىٰٓ ﴿٨﴾
96:8 Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
أَرَءَيْتَ ٱلَّذِى يَنْهَىٰ ﴿٩﴾
96:9 Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀
عَبْدًا إِذَا صَلَّىٰٓ ﴿١٠﴾
96:10 fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!
أَرَءَيْتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلْهُدَىٰٓ ﴿١١﴾
96:11 Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)
أَوْ أَمَرَ بِٱلتَّقْوَىٰٓ ﴿١٢﴾
96:12 tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!
أَرَءَيْتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ ﴿١٣﴾
96:13 Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?
أَلَمْ يَعْلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ ﴿١٤﴾
96:14 Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)
كَلَّا لَئِن لَّمْ يَنتَهِ لَنَسْفَعًۢا بِٱلنَّاصِيَةِ ﴿١٥﴾
96:15 Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí. Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí2 rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);
نَاصِيَةٍ كَـٰذِبَةٍ خَاطِئَةٍ ﴿١٦﴾
96:16 àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
فَلْيَدْعُ نَادِيَهُۥ ﴿١٧﴾
96:17 Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.
سَنَدْعُ ٱلزَّبَانِيَةَ ﴿١٨﴾
96:18 Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.
كَلَّا لَا تُطِعْهُ وَٱسْجُدْ وَٱقْتَرِب ۩ ﴿١٩﴾
96:19 Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).