بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَـٰنِ ٱلرَّحِيمِ
لَآ أُقْسِمُ بِهَـٰذَا ٱلْبَلَدِ ﴿١﴾
90:1 Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìíbúra.
وَأَنتَ حِلٌّۢ بِهَـٰذَا ٱلْبَلَدِ ﴿٢﴾
90:2 Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).1
وَوَالِدٍ وَمَا وَلَدَ ﴿٣﴾
90:3 Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.
لَقَدْ خَلَقْنَا ٱلْإِنسَـٰنَ فِى كَبَدٍ ﴿٤﴾
90:4 Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.
أَيَحْسَبُ أَن لَّن يَقْدِرَ عَلَيْهِ أَحَدٌ ﴿٥﴾
90:5 Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?
يَقُولُ أَهْلَكْتُ مَالًا لُّبَدًا ﴿٦﴾
90:6 Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”
أَيَحْسَبُ أَن لَّمْ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ ﴿٧﴾
90:7 Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?
أَلَمْ نَجْعَل لَّهُۥ عَيْنَيْنِ ﴿٨﴾
90:8 Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?
وَلِسَانًا وَشَفَتَيْنِ ﴿٩﴾
90:9 Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?
وَهَدَيْنَـٰهُ ٱلنَّجْدَيْنِ ﴿١٠﴾
90:10 A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.
فَلَا ٱقْتَحَمَ ٱلْعَقَبَةَ ﴿١١﴾
90:11 Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلْعَقَبَةُ ﴿١٢﴾
90:12 Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?
فَكُّ رَقَبَةٍ ﴿١٣﴾
90:13 (Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.
أَوْ إِطْعَـٰمٌ فِى يَوْمٍ ذِى مَسْغَبَةٍ ﴿١٤﴾
90:14 Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.
يَتِيمًا ذَا مَقْرَبَةٍ ﴿١٥﴾
90:15 (Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,
أَوْ مِسْكِينًا ذَا مَتْرَبَةٍ ﴿١٦﴾
90:16 tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).
ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَتَوَاصَوْا۟ بِٱلصَّبْرِ وَتَوَاصَوْا۟ بِٱلْمَرْحَمَةِ ﴿١٧﴾
90:17 Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.
أُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ ﴿١٨﴾
90:18 Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا هُمْ أَصْحَـٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ ﴿١٩﴾
90:19 Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.1
عَلَيْهِمْ نَارٌ مُّؤْصَدَةٌۢ ﴿٢٠﴾
90:20 Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.