بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَـٰنِ ٱلرَّحِيمِ
ٱلْقَارِعَةُ ﴿١﴾
101:1 Àkókò ìjáyà.
مَا ٱلْقَارِعَةُ ﴿٢﴾
101:2 Kí ni Àkókò ìjáyà?
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلْقَارِعَةُ ﴿٣﴾
101:3 Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà?
يَوْمَ يَكُونُ ٱلنَّاسُ كَٱلْفَرَاشِ ٱلْمَبْثُوثِ ﴿٤﴾
101:4 (Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta,
وَتَكُونُ ٱلْجِبَالُ كَٱلْعِهْنِ ٱلْمَنفُوشِ ﴿٥﴾
101:5 àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù.
فَأَمَّا مَن ثَقُلَتْ مَوَٰزِينُهُۥ ﴿٦﴾
101:6 Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n,
فَهُوَ فِى عِيشَةٍ رَّاضِيَةٍ ﴿٧﴾
101:7 ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí.
وَأَمَّا مَنْ خَفَّتْ مَوَٰزِينُهُۥ ﴿٨﴾
101:8 Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́,
فَأُمُّهُۥ هَاوِيَةٌ ﴿٩﴾
101:9 Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀.
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا هِيَهْ ﴿١٠﴾
101:10 Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?
نَارٌ حَامِيَةٌۢ ﴿١١﴾
101:11 (Òhun ni) Iná gbígbóná tó ń jó gan-an.