QuranQuiz bySALSABIL STUDIO
Open the appOpen app

سورة العاديات

Surah Al-'Adiyat in Yoruba

11 ayat · Meccan · Surah 100 of 114

🌐 Translation: Yorùbá

Englishالعربية (بلا ترجمة)اردوBahasa IndonesiaBahasa MelayuTürkçeFrançaisDeutschEspañolPortuguêsItalianoNederlandsРусскийفارسیবাংলাहिन्दीSoomaaliKiswahiliHausaShqipBosanskiAzərbaycancaOʻzbekcha中文日本語한국어ภาษาไทยTiếng ViệtTagalogپښتوPolskiSvenskaNorskSuomiČeštinaRomânăБългарскиУкраїнськаעבריתதமிழ்മലയാളംతెలుగుमराठीગુજરાતીनेपालीසිංහලঅসমীয়াسنڌيدریKurdîދިވެހިئۇيغۇرچەአማርኛAfaan OromooYorùbáKinyarwandaBamanankanChiyaoTamaziɣtMëranawТоҷикӣҚазақшаТатарчаភាសាខ្មែរEnglish (Abdel Haleem)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَـٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلْعَـٰدِيَـٰتِ ضَبْحًا ﴿١﴾

100:1 Allāhu fi àwọn ẹṣin tó ń sáré tó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun búra.

فَٱلْمُورِيَـٰتِ قَدْحًا ﴿٢﴾

100:2 Ó tún fi àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) búra.

فَٱلْمُغِيرَٰتِ صُبْحًا ﴿٣﴾

100:3 Ó tún fi àwọn ẹṣin tó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù búra.

فَأَثَرْنَ بِهِۦ نَقْعًا ﴿٤﴾

100:4 Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.

فَوَسَطْنَ بِهِۦ جَمْعًا ﴿٥﴾

100:5 Wọ́n tún bẹ́ gìjà pẹ̀lú eruku ẹsẹ̀ wọn sáààrin àkójọ ọ̀tá.

إِنَّ ٱلْإِنسَـٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٌ ﴿٦﴾

100:6 Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.

وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٌ ﴿٧﴾

100:7 Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.

وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلْخَيْرِ لَشَدِيدٌ ﴿٨﴾

100:8 Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.

۞ أَفَلَا يَعْلَمُ إِذَا بُعْثِرَ مَا فِى ٱلْقُبُورِ ﴿٩﴾

100:9 Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),

وَحُصِّلَ مَا فِى ٱلصُّدُورِ ﴿١٠﴾

100:10 tí wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,

إِنَّ رَبَّهُم بِهِمْ يَوْمَئِذٍ لَّخَبِيرٌۢ ﴿١١﴾

100:11 dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?

Do you really know Surah Al-'Adiyat by heart?

A short test shows exactly where you slip. No sign-up, free.

Start the test

Hear Surah Al-'Adiyat from all 90 reciters →