QuranQuiz bySALSABIL STUDIO
Open the appOpen app

سورة التكوير

Surah At-Takwir in Yoruba

29 ayat · Meccan · Surah 81 of 114

🌐 Translation: Yorùbá

Englishالعربية (بلا ترجمة)اردوBahasa IndonesiaBahasa MelayuTürkçeFrançaisDeutschEspañolPortuguêsItalianoNederlandsРусскийفارسیবাংলাहिन्दीSoomaaliKiswahiliHausaShqipBosanskiAzərbaycancaOʻzbekcha中文日本語한국어ภาษาไทยTiếng ViệtTagalogپښتوPolskiSvenskaNorskSuomiČeštinaRomânăБългарскиУкраїнськаעבריתதமிழ்മലയാളംతెలుగుमराठीગુજરાતીनेपालीසිංහලঅসমীয়াسنڌيدریKurdîދިވެހިئۇيغۇرچەአማርኛAfaan OromooYorùbáKinyarwandaBamanankanChiyaoTamaziɣtMëranawТоҷикӣҚазақшаТатарчаភាសាខ្មែរEnglish (Abdel Haleem)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَـٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا ٱلشَّمْسُ كُوِّرَتْ ﴿١﴾

81:1 Nígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,

وَإِذَا ٱلنُّجُومُ ٱنكَدَرَتْ ﴿٢﴾

81:2 àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

وَإِذَا ٱلْجِبَالُ سُيِّرَتْ ﴿٣﴾

81:3 àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),

وَإِذَا ٱلْعِشَارُ عُطِّلَتْ ﴿٤﴾

81:4 àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,

وَإِذَا ٱلْوُحُوشُ حُشِرَتْ ﴿٥﴾

81:5 àti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,

وَإِذَا ٱلْبِحَارُ سُجِّرَتْ ﴿٦﴾

81:6 àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,

وَإِذَا ٱلنُّفُوسُ زُوِّجَتْ ﴿٧﴾

81:7 àti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)

وَإِذَا ٱلْمَوْءُۥدَةُ سُئِلَتْ ﴿٨﴾

81:8 àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé

بِأَىِّ ذَنۢبٍ قُتِلَتْ ﴿٩﴾

81:9 ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,

وَإِذَا ٱلصُّحُفُ نُشِرَتْ ﴿١٠﴾

81:10 àti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,

وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ كُشِطَتْ ﴿١١﴾

81:11 àti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,

وَإِذَا ٱلْجَحِيمُ سُعِّرَتْ ﴿١٢﴾

81:12 àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,

وَإِذَا ٱلْجَنَّةُ أُزْلِفَتْ ﴿١٣﴾

81:13 àti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),

عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّآ أَحْضَرَتْ ﴿١٤﴾

81:14 (nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).

فَلَآ أُقْسِمُ بِٱلْخُنَّسِ ﴿١٥﴾

81:15 Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,

ٱلْجَوَارِ ٱلْكُنَّسِ ﴿١٦﴾

81:16 (ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.

وَٱلَّيْلِ إِذَا عَسْعَسَ ﴿١٧﴾

81:17 Mo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.1

وَٱلصُّبْحِ إِذَا تَنَفَّسَ ﴿١٨﴾

81:18 Mo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.

إِنَّهُۥ لَقَوْلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ ﴿١٩﴾

81:19 Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,1

ذِى قُوَّةٍ عِندَ ذِى ٱلْعَرْشِ مَكِينٍ ﴿٢٠﴾

81:20 alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,

مُّطَاعٍ ثَمَّ أَمِينٍ ﴿٢١﴾

81:21 ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.

وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجْنُونٍ ﴿٢٢﴾

81:22 Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.

وَلَقَدْ رَءَاهُ بِٱلْأُفُقِ ٱلْمُبِينِ ﴿٢٣﴾

81:23 Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.1

وَمَا هُوَ عَلَى ٱلْغَيْبِ بِضَنِينٍ ﴿٢٤﴾

81:24 Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).

وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَيْطَـٰنٍ رَّجِيمٍ ﴿٢٥﴾

81:25 Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.

فَأَيْنَ تَذْهَبُونَ ﴿٢٦﴾

81:26 Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?

إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَـٰلَمِينَ ﴿٢٧﴾

81:27 Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

لِمَن شَآءَ مِنكُمْ أَن يَسْتَقِيمَ ﴿٢٨﴾

81:28 (Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.

وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلْعَـٰلَمِينَ ﴿٢٩﴾

81:29 Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Do you really know Surah At-Takwir by heart?

A short test shows exactly where you slip. No sign-up, free.

Start the test

Hear Surah At-Takwir from all 90 reciters →